Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC Ti Ìpínlẹ̀ Kano Wà Lẹ́yìn Ààrẹ Tinubu, Gómìnà Yusuf Fún Ìdìbò Ọdún 2027

37

 

Àwọn alenulọ́rọ̀ ẹgbẹ́ All Progressives Congress (APC) tí agbègbè Ariwa ìgbìmọ̀ aṣòfin ti ìlú Kano ti ṣe ìlérí láti kó ìtìlẹ́yìn ńlá fún Ààrẹ Bola Tinubu, Gómìnà Abba Yusuf àti Igbákejì Ààrẹ ti Ìgbìmọ̀ aṣòfin, Barau Jibrin, jọ nínú ìdìbò gbogbogbòò ti ọdún 2027.

A rí ìpéjọpọ̀ náà gẹ́gẹ́ bí apá kan nínú ìṣọ̀kan ìṣèlū bí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú pàtàkì ṣe ń bẹ̀rẹ̀ sí í so ara won pọ̀ kí ó tó di ọdún 2027.

Nígbà tí ó ń bá àwọn olùkópa sọ̀rọ̀, Igbákejì Ààrẹ Ìgbìmọ̀ aṣòfin, Sẹ́nétọ̀ Barau Jibrin, sọ pé ìpàdé náà jẹ́ láti mú kí ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ náà lágbára síi àti láti mú kí àwọn ẹgbẹ́ APC lágbára síi ní Ìpínlẹ̀ Kano, ibi ìdúró òṣèlú pàtàkì ní àríwá Nàìjíríà.

Gẹ́gẹ́ bí apá kan ìsapá láti mú kí àwọn ènìyàn túbọ̀ máa bá ara wọn ṣiṣẹ́ pọ̀ sí i, Sẹ́nétọ̀ Barau kéde pé wọ́n ti fi ọkọ̀ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n àti kẹ̀kẹ́ okanlelogoje,141 fún àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀, àwọn igbákejì alága, àwọn ìgbìmọ̀ àti àwọn akọ̀wé káàkiri àwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàlá ní ariwa Kano.

Àwọn alága àti igbákejì alága yóò gba ọkọ̀, nígbà tí àwọn ìgbìmọ̀ àti àwọn akọ̀wé yóò ní ìtìlẹ́yìn pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ láti mú kí ìṣọ̀kan àti ipolongo ibo àti gbogbo ibi ti wọn fẹ lọ leè dẹrùn.

Ìpàdé náà ṣèlérí láti mú kí ìsapá ìgbìmọ̀ pọ̀ sí i ní ariwa Kano, kí ó sì gbé agbègbè náà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ pàtàkì sí ètò ìdìbò gbogbogbòò ti APC fún ìdìbò gbogbogbòò ọdún 2027.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button