Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Ìṣẹ́ DHQ Bu Ẹnu Àtẹ́ Lu Ikọ̀lù Ìpínlẹ̀ Kwara

19

 

Ilé Iṣẹ Defence Headquarters (DHQ) ti kẹ́dùn, wọn sì ti bu ẹnu àtẹ́ lu ikọlu sì àwọn ènìyàn àti agbègbè Wòrò ní ìjọba ìbílẹ̀ Kaiama ní ìpínlè Kwara níbití ọpọlọpọ ènìyàn ti gbẹ̀mi mì.

 

Nínú àkọsílẹ̀ kan, ọgá agba ilé iṣẹ eto ààbò àti irohin, Ọ̀gágun Samaila Uba sọ pé ajọ Armed Forces of Nigeria (AFN) gboriyin fún iṣọkan àwọn ọmọ Nàìjíríà ti àwọn ẹsinòkọkú gbìnàyá. Ti àwọn ènìyàn kò faye gbà kí àwọn ènìyàn buruku náà
láti yí wọn lọkan padà nípa ẹ̀ṣìn àti láti máa ṣe ibi.

 

“Ìṣọ̀kan ati ìpamọ́ra àwọn ọmọ orílẹ-èdè yìí ní a nilati dáàbòbò lọ́wọ́ àwọn ọtá tó fẹ bá àlàáfíà àti isokan Nàìjíríà jẹ ,” DHQ sọ èyí.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button