Ààrẹ Bola Tinubu ti jẹjẹ pé orílẹ-èdè Naijiria kò ní tẹriba fún àwọn Ẹsinòkọkú alájàngbilà, wipe orílẹ-èdè yìí yóò daabobo àwọn èniyàn àti iyì wọn titi dòpin latari àwọn onipanle to fẹ fi tipatipa yì ẹsìn àwọn ènìyàn padà.
Ààrẹ sọ èyí lórí ẹrọ ayélujára “X” rẹ ní Ana lẹyìn ikọ̀lù burúkú sì agbegbe Worro ni Kaiama, ipinlẹ Kwara. Ààrẹ ri Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq, ẹni to salaye fun nipa iṣẹ to buru jai náà.
Ààrẹ sọ di mimọ pé oun ti rán ikọ̀ ọ̀wọ́ ọmọ ogun ní waransesa
lọ sí ìjoba ìbílẹ̀ Kaiama lẹyìn ikọ̀lù sì àwọn ènìyàn ti ko mọwọ́ mẹsẹ̀.
Ààrẹ sọ siwaju pé oun ti rán àwọn alenuloro láti jẹ kí àjọṣepọ wà láàárín ipinlẹ àti ìjọba àpapọ láti rán wọn lọwọ pẹlu àwọn nnkan itura fún agbègbè náà àti pé wọn yóò fi ọwọ́ sinkun òfin mú àwọn ẹni ibi náà laipẹ́.
“ Wọn kò ní lọ, a máa ri wọn mú,” ààrẹ fi kun.
Ó wà jẹjẹ pé ìjọba rẹ̀ yóò dáàbòbo àgbègbè náà, wọn yóò sì ṣẹgun àwọn to fẹ pín orile-ede yìí.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san