Ààrẹ Tinubu gbóríyìn fún ẹgbẹ́ Super Eagles fún àṣeyọrí ipò kẹta ní AFCON
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ Bola Tinubu ti gbóríyìn fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Nàìjíríà, Super Eagles, bí wọn kò ṣe jé kí ìjákulẹ̀ ìpele kan kótó kan ti ìpari pẹ̀lú orílẹ̀-èdè tó gbàlejò ìfigagbága náà, Morocco dí wọn lọ́wọ́ láti gbé ipò kẹta nínú ife orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀ 2025.
Ninu ifiranṣẹ oriire ti Aarẹ fi sita ni ọjọ Abamẹta, o sọ pe bi ẹgbẹ naa ṣe gbe ipo kẹta ṣafihan ifarasi, ipinnu ati igbamọra Naijiria lori bọọlu gbigba.
Aarẹ Tinubu wa sọ pe aṣeyege ẹgbẹ Super Eagles tun wa fi ifarasi, itẹramọ ati ọkan pe mo le ṣee ti gbogbo eniyan mọ pẹlu orilẹ-ede wa han.
Aarẹ tun wa sọ ninu ọrọ rẹ pe bi Super Eagles ṣe ja fitafita to lasiko ifigagbaga naa, wọn ja kulẹ ni ipele kan ki o to kan ipele ipari lasiko ti wọn koju Morocco, ni Ọjọọru.
‘Wọn mori wa wu bi wọn ṣe n gba fadaka wọn ni ọjọ Aiku ni, Rabat Morocco.
Ẹgbẹ Super Eagles fajulọ han Egypt, ti wọn si gbe awọn ti wọn ti gba ife AFCON lẹemeje ṣubu, pẹlu bọọlu ojukoju lẹyin asiko to yẹ , ti ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria si bori.