Take a fresh look at your lifestyle.

Ọmọ Atíkù Abubakar Darapọ̀ Mọ́ Ẹgbẹ́ Òsèlú APC

101

 

Ọmọ igbákejì ààrẹ orílẹ-èdè yìí tẹ́lẹ̀ ri ti kuro nínú egbẹ́ Peoples Democratic Party (PDP) ti lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), tó sì faramọ́ ìpadàbọ̀ ààrẹ Bola Tinubu leekeji.

Ọ̀gbẹ́ni Abubakar ní wọn gbà t’ọwọ́ tẹsẹ̀ ní ojó Ọjọ́rú ní gbọ̀gàn National Assembly látọwọ́ igbákejì ààrẹ Ilé igbimọ̀ aṣòfin, Barau Jibrin àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ míràn lati ẹkùn ìwọ̀ -oòrùn Àríwá.

Ó sọ pé ìdí ti òun fi darapọ̀ ní pé ìṣàkóso àìlẹ́gbẹ́ ti igbákejì aare Ilé igbimọ̀ aṣòfin,Barau I. Jibrin.”wú oun lórí jọjọ.

Igbakeji ààrẹ Ilé igbimọ̀ aṣòfin yin ọ̀gbẹ́ni Abubakar fún èròngbà rẹ̀ láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́, pé kò wá bá bàbá rẹ̀, o mọ́gbọ́n wá bóṣe wá, ó ní ìgbàgbọ́ ninu ètò ààrẹ- ìrètí ọ̀tun. Ó tún jẹ́ ọ̀dọ́ tó ní àfojúsùn rere ti orílẹ-èdè yìí nilò ti yóò tun ọjọ́ ọ̀la orílẹ-èdè yìí ṣe.

Temitope Obisesan

Comments are closed.

button