Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti kéde Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja gẹ́gẹ́ bíi Alága Ìgbìmọ̀ Lọ́ba-lọ́ba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Gómìnà Seyi Makinde ti fi lédè pé jíjẹ oyè alága ìgbìmọ̀ Lọ́ba-lọ́ba yóò máa wáyé lẹẹkan lọ́dún méjì láàrin Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Sòún Ogbomoso àti Aláàfin Ọ̀yọ́.
Gómìnà ló fi ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ níbi ìpàdé tó wáyé ni gbọ̀ngàn àwọn Lọ́ba-lọ́ba tó wá ni Ilé iṣẹ́ ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó wà ni Agodi, ni ìlú Ìbàdàn tii ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Nínú ìpàdé yìí ni Gómìnà àti àwọn ọba Aládé náà ti fikùn-lukùn lati fi òpin sí awuyewuye to n súyọ lórí jíjẹ oyè alága ìgbìmọ̀ yìí, nínú èyí tí wọn fi ohun ṣọ̀kan láti ṣe àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ Lọ́ba-lọ́ba nígbà ti Gómìnà tọ́ka Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja, Arusa I gẹ́gẹ́ bíi Alága ìgbìmọ̀.
Ìgbésẹ yìí náà lo ṣe àfihàn ọgbọ́n inú Gómìnà Makinde láti fi òpin sí awuyewuye eléyìí tó súyọ látàrí tani yóò máa jẹ́ alága ìgbìmọ̀ Lọ́ba-lọ́ba ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Nígbà to n fi ọkàn imoore hàn fún ìgbésẹ pàtàkì yìí, Ọba Ladoja dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti lọ́wọ́ àwọn ọba ẹgbẹ́ rẹ̀ fún ìsọ̀kan àti ìkúnlọ́wọ́ wọn. Ọba Ladoja wa fi dá gbogbo wọn lójú pé àfojúsùn ìgbìmọ̀ Lọ́ba-lọ́ba ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni yóò dá lórí wíwá àlàáfíà, ètò ààbò, ìpamọ́ àti ìlọsíwájú agbègbè ẹnikọọkan wọn.
Abiola Olowe,
Ìbàdàn