Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà Tún Ṣé Ìdánilójú Ìdúróṣinṣin Sí Ètò Ẹ̀kọ́ Àwọn Ọmọ-kékeré ‎

78

‎Ìjọba Nàìjíríà tí tún ṣé ìdánilójú ìdúróṣinṣin fún ìtọ́jú ẹ̀kọ́ àti ìdàgbàsókè àwọn ọmọ-kékeré (ECCDE) lágbára gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tó dára àti ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè.

‎ Mínísítà fún ẹ̀kọ́, Dókítà Tunji Alausa sọ èyí nínú ọ̀rọ̀ ìkíni rẹ̀ níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ ìbánisọ̀rọ̀ ọdọọdún tí ‘Early Child Care And Development Education ECCDE’, tí a ṣe ní Abuja pẹ̀lú àwọn alẹnu-lọrọ láti gbogbo ẹ̀ka ẹ̀kọ́.

‎ Mínísítà náà ṣàpèjúwe ECCDE gẹ́gẹ́ bí èyí tó ṣe pàtàkì sí ìdàgbàsókè ìmọ̀, àwùjọ àti ti ara àwọn ọmọdé, ó sì kíyèsí pé Ilé-iṣẹ́ náà ṣì ń darí ètò ìṣèlú orílẹ̀-èdè lórí ẹ̀kọ́ àti ìlànà ECCDE ti orílẹ̀-èdè.

Comments are closed.

button