Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Dókítà bèèrè fún ìgbàpadà àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n dá dúró lẹ́nu iṣẹ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

184

Ikọ̀ Àringbùngbùn –Àrewa ti Ẹgbẹ́ àwọn Àgbàa Dókítà (ARD), ti panupọ̀ béèrè fún gbígbà padà àwọn ẹlegbẹ́ wọn tí wọ́n dá dúró lẹ́nu iṣẹ́ ní Ilé Ìwòsàn Olùkọ́ni tìjọba àpapọ̀ (FTH), ti Lokoja, ní ìpínlẹ̀ Kogi, ní ọjọ́ Ẹtì.

Adari ikọ naa. Dokita  Fanen Dogoh, nibi apejọ awọn akọroyin ni Abuja, sọ pe wọn da awọn dokita yii duro lẹnu iṣe lori ẹsun pe wọn fi ẹhonu han lọna aitọ ati awọn eto ẹgbẹ, ti o si ṣapejuwe eyi bii aiṣedeede.

Dogoh ṣalaye pe ikọ Aringbungbun- Arewa mọ pe ọpọlọpọ igbimọ ni wọn ti gbe dide lati ṣe agbeyewo ọrọ naa, ti gbogbo wọn si ṣe agbekalẹ ki wọn gba awọn dokita ti ọrọ naa kan pada.

O wa pakiyesi pe, pẹlu awọn agbekalẹ ati akọsilẹ igbọraẹni ye (MoU) ti o wa laarin ijọba apapọ ati Egbẹ awọn Agba Dokita lapapọ (NARD), ti wọn buwọlu lasiko ipade ti wọn ṣe gbẹyin, ijọba ko gbe igbesẹ kankan lori ẹ.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ikọ naa tun sọrọ lori awọn owo kereke ati eyi ti wọn ti jẹ awọn Agba dokita tẹlẹ laisan jake jado awọn ile iwosan ijọba apapọ.

O kanlẹ da orukọ Awọn agba dokita ile iwosan olukọni ijọba apapọ, Makurdi, ipinlẹ Benue ati tipinlẹ Kwara ti wọn ti jẹ ni owo oṣu mejidin-logun sẹyin ati awọn owo kereje.

Dogoh wa rọ ijọba apapọ lati ṣatunṣe lori gbogbo ọrọ ti wọn ka silẹ lasiko ibaraẹnisọrọ rẹ pẹlu awọn agba dokita NARD naa, ti o si kilọ pe laijẹ bẹ, iyanṣẹ lodi yoo waye fun gbogbo awọn agba dokita jake jado orilẹ-ede.

O tẹ siwaju pe ẹgbẹ naa yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi ni ọjọ Aje, ọjọ kejila, oṣu kinni, ti ijọba ko ba ṣe ohun ti wọn jọ fẹnu ko le.

 

Comments are closed.

button