Gómìnà ìpínlẹ̀ Akwa Ibom Olùṣọ Àgùntàn Uma Eno ti pe àwọn ará ìlú ati àwọn Olóṣèlú láti jẹ ki Àlàáfíà Joba Lásìkò Ìdìbò Odun 2027.
Gómìnà mu amoran àlàáfíà yìí wa lasiko ti wọn se idupe ọdun tuntun ni gbo gán International Worship ni ìpínlè uyo.
Gómìnà gboriyin fún àwọn Olóṣèlú fún ọgbọ́n àti òye ti won fi n tó ilú láti lé jẹ ki Àlàáfíà ati isokan joba laarin àwọn ènìyàn ìlú, pàápàá jùlọ ni ìpínlẹ̀ Akwa Ibom.
Bákanáà ó rọ àwọn èèyàn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lati sise po pẹ̀lú áwọn olóṣèlú fún ìfẹ to ye koro.
Ò wa fi àsìkò náà pe àwọn Kristẹni láti ni èmi ìrẹlẹ, iṣọkan ati ifọkansi, ki wọn sì gbe ọkàn le Ọlọrun Oba.
Alága pata fún ẹgbẹ́ àwọn onígbàgbọ ni ìpínlẹ̀ naaa Bísọ̀bù Christ Nyon dupe lọwọ Gómìnà bi o ṣe n fi àpẹẹrẹ rere àlàáfíà hàn nínú eto ijoba rẹ, o sí rọ àwọn ènìyàn láti ṣe atilẹyin fún.