Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Plateau kí àwọn aṣojú PDP káàbọ̀ fún àpèjọ Àríwá Àringbùngbùn

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

91

Gómìnà ìpínlẹ̀ Plateau, Caleb Mutfwang, ti gba àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) láti Àríwá Àringbùngbùn  lálejò fún oúnjẹ alẹ́ kí  ìpàdé agbègbè ẹgbẹ́ láti yan àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tuntun tó bẹ̀rẹ̀.

Nigba ti o n sọrọ nibi apejẹ ounjẹ alẹ naa ti o waye ni gbọngan igbalejo ti ile ijọba tuntuntu, Rayfield, Gomina Mutfwang fi idunnu rẹ han si awọn aṣoju fún ìfaradà, ìṣọ̀kan, àti ìdúróṣinṣin wọn sí ẹgbẹ́ náà láìka ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpèníjà si.

O wa fi da won loju wi pe ẹgbẹ oṣelu PDP wa loju ona lati di alagbara, tunbọ ni isokan, ati ní ipo ti o dara ju fun awon iṣẹgun ninu eto idibo ojo iwaju.

Nigba ti o n ṣapejuwe ẹgbẹ PDP gẹgẹ bi ọkan ninu awọn ẹgbẹ oṣelu ti o ṣẹtọ julọ, ti o da lori eniyan, ati ti o da lori ero-imọran ti awọn ẹgbẹ oṣelu Naijiria ti ri lati igba ijọba olominira Keji, Gomina tun wa tẹnumọ iwulo lati tun ẹgbẹ naa ṣe nitori idibo ọjọ iwaju.

Ó gbóríyìn fún ọkàn akin àwọn ará Plateau lori àwọn ìdájọ́ tí wọ́n ṣe tí wọ́n fi lé  àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀-èdè àti àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógún danu.

Ni riranti ifarasin ti wọn fihan lasiko idibo gbogbogboo ọdun 2023, o sọ pe awọn eniyan ṣafihan ifọkansi ati igbiyanju lati faaye gba iṣakoso to nipa.

Comments are closed.

button