Ààrẹ Bola Tinubu ti ki olokiki agbẹnusọ alatilẹyin tiwantiwa ti o tun jẹ agbẹjọro, Omidan Ayo Obe, kú àjọ̀dún ọjọ́bìí ààdọ́rin ọdún.
Ile iṣẹ Ààrẹ sọ ninu alaye kan pe Aarẹ Tinubu gboriyin fun amofin naa fun iṣafihan deede fun ifẹ orilẹ-ede ati ẹda eniyan, eroja ti o ṣalaye iṣe aye ati itiraka fun ododo ati awujọ to daraju.
“Mo ranti ipa rẹ si ijọba tiwantiwa pẹlu imuyangan, ti o si jẹ pe loni yii, a duro lori idagbasoke ati ifidi rinlẹ rẹ,” Aarẹ Tinubu sọ bayii.
Ayo Obe, alugbeja fun ẹtọ ọmọniyan, ti jẹ Adari ẹgbẹ ti n ja fun ọminira ara ilu (CLO) ri, Ẹgbẹ ti n mojuto iyipada ijọba ni Naijiria, Ọmọ ẹgbẹ igbimọ awọn oṣiṣẹ agbofinro, ti o si tun ṣadari eto idibo ile iṣẹ ijọba tiwantiwa ni Abuja laarin 2006- 2009, ni awọn igba ọtọọtọ.
Aarẹ wa gbadura ki Ọlọrun Alagbara tunbọ fun ni alaafia to dangaajia ati ẹmi to dara ki o le tunbọ le sin orilẹ-ede nipasẹ igbẹnusọ rẹ fun awujọ to dara julọ ati ẹda ọmọniyan.