Àwọn Amòfin Fọwọ́ Sí Yíyan Gómìnà Ìpínlẹ̀ Katsina Lẹ́kàn Si
Àwọn amòfin láti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Katsina ti fọwọ́ sì yíyan gómìnà Umar Radda fún ìgbà kejì ní orí àlééfà.
Ìbuwọ́lù náà wáyé láti ọwọ́ ẹgbẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), látàrí ìbò àpapọ̀ ọdún 2027 tó ń bọ.
Ọ́nárébù Sada Soli tó ń sojú fún ẹ̀ka ìjọba àpapọ̀ Jibia àti Kaita ló sọ èyí ní ìlú Abuja bí àwọn ẹgbẹ́ ti rán an ní ilé ìgbìmọ̀ asojú sòfin.
Ó gbóríyìn fún ìdarí ọgbẹ́ni Radda gẹ́gẹ́ bí èyí to ní èròngbà rere tó sì kòni mọ́ra.
Solo fi kun bí ìjọba rẹ̀ ṣe máa ń gbógun ti àwọn Ọ̀daràn, ó ń ṣisẹ́ lórí àtúnṣe ètò ẹ̀kọ́, ìmúgbóòrò ètò ọ̀gbìn, ìdàgbàsókè olókòwò, mímú agbègbè wà ní ìrẹ́pọ̀ àti ìbágbépọ̀ àlàáfíà.
Àwọn amòfin, afọbajẹ náà ṣèlérí àtìlẹ́yìn àti òdodo wọn fún ìṣèjọba gómìnà ní igbà keji, nígbà ti wọn wà rọ gbogbo àwọn afẹ́nifẹ́re ọmọ ìpínlẹ̀ Katsina láti jẹ́ kí ohun rere tó ti bẹ̀rẹ̀ nípasẹ̀ ìṣèjọba rẹ̀ kò tẹ̀ẹ̀ síwájú kí ìlọsíwájú leè bá ìpínlẹ̀ Katsina.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san