Olùdíje Gómìnà fún ẹgbẹ́ òṣèlú Labour (LP), ti ìpínlẹ̀ Anambra, Ọ̀gbẹ́ni George Moghalu, ti bẹnuàtẹ́ lu ìṣẹ̀lẹ̀ aburú pí́pa Ààrẹ- gbogbogbòò agbègbè Aguleri ti agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Gusu Anambra, Ọ̀gbẹ́ni Ifeanyi Iloakasia, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Rolex.
Iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni asiko diẹ lẹyin ijoko gbejọ ni ile ẹjọ ninu igboro Ekwulobia.
Ọgbeni Moghalu wa koro oju si ipa ika naa ninu alaye kan to fi sita fun awọn akọroyin ni Awka.
Ti o si ṣapejuwe ikọlu naa bii “iṣojo ati igbero,” Moghalu bẹnu atẹ lu pe o jẹ ifasẹyin to lagbara fun idajọ, alaafia, ati iṣakoso agbegbe ni ipinlẹ Anambra.
O wa pe fun iyara ati iwadi to jinlẹ lori iṣẹlẹ naa, ti o si tun n sọrọ lori bi ọrọ aabo ṣe n mẹhẹ nipa ikọlu ipa jake jado ipinlẹ naa leralera.
Alakoso Oludari ti ile iṣẹ ti n risi awọn ọna omi loke ilẹ lorilẹ-ede (NIWA) to ṣẹṣẹ kuro lori oye, wa rọ awọn ile iṣẹ aabo lati teramọ akitiyan lati mu ẹni ti o ṣe iṣe laabi naa.
Nigba ti o n tunbọ fidi ipinnu ti ko labaawọn rẹ si alaafia ati idajọ mulẹ, Moghalu duro lori pe igbiyanju ẹni ti o pa arakunrin naa lati pa ẹnu idajọ ododo mọ ko ni yege.