Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu túnbọ̀ fìdí ìpinnu rẹ̀ múlẹ̀ lóri ìfọ̀rọ̀jomitoro ọ̀rọ̀ láàrin ẹlẹ́sìn, ìgbàmọ́ra lágbàáyé

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

39

Adarí Nàìjíríà, Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti túnbọ̀ fìdí ìpinnu rẹ̀ múlẹ̀ lóri ìṣàgbélárugẹ àjọṣepọ̀ ìfọ̀rọ̀jomitoro ọ̀rọ̀ láàrin Àwọn ẹlẹ́sìn, ìgbàmọ́ra, àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ jákèjádò lágbàáyé

Ààrẹ naa tun wa sọ pe Naijiria ṣi jẹ orilẹ-ede to ṣatẹwọgba irẹpọ, to ni igbagbọ to rinlẹ, ti o si wa ni ipo pe o ni agbọye jake jado agbaye.

Ààrẹ Tinubu ti Akọwe fun orilẹ-ede si olu ilu Roomu, Ẹni Apọnle Kadinali Pietro Parolin pe sibi ounjẹ alẹ bi o ṣe de si Roomu, ni o sọ eyi di mimọ latori ayalujara rẹ X handle@officialABAT.

Adari Naijiria wa sọ pe ijumọsọrọ oun ati Akọwe fun orilẹ-ede si olu ilu Roomu, waye latari ẹmi ajọṣepọ ẹgbẹ ati ipinnu kannaa ti awọn jọ ni fun ọjọ iwaju.

O tun wa sọ pe ipade naa tun jẹ fun iyi tawọn jọ ti fun alaafia, ibọwọ funra eni, ati iṣọkan agbaye.

Comments are closed.

button