Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu, àwọn adarí àgbáyé kópa nínú ìgorí ìtẹ́ Pope Leo kẹrìnlá

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

36

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti darapọ̀ mọ́ àwọn adarí lágbàáyé ni St Peter’s Basilica fún ìgorí ìtẹ́ Pope Leo kẹrìnlá, tí ó fi ìgbà kan jẹ́ àdarí Kadinali Robert Francis Prevost, ó jẹ́ ọmọ bíbí inú  Chicago, tí ó sì tún jẹ́ olùjọ́sìn St. Augustine.

 

Akọkọ ọmọ Amẹrika ti yoo jẹ Poopu bẹrẹ irin ajo igori oye ti gbọngan St. Pete ni ọjọ Aiku, ninu ọkọ ayọkẹlẹ Poopu, ti o si n ki awọn ogunlọgọ arinrin ajo mimọ ati awọn ololufe rẹ ki ijọsin iwuye to bẹrẹ.

Adari Naijiria, Ààrẹ Tinubu darapọ mọ ọpọlọpọ adari lagbaaye, pẹlu Alakoso orilẹ -ede Kanada Mark Carney, igbakeji Aarẹ Amẹrika JD Vance, Aarẹ orilẹ-ede Argentina,  Javier Milei, ati igbakeji Aarẹ orilẹ-ede Brazil, Geraldo Alckmin ati awọn miiran, ni gbagede St. Peter lati kopa ninu ayẹyẹ ti o bẹrẹ ni agogo mẹwaa owurọ (Ti o jẹ agogo mẹjọ lamẹrika).

 

Ayẹyẹ yii ni o ṣe isami ibẹrẹ iṣẹ iwaasu Ẹni mimọ Pope Leo kẹrinla, ti o jẹ Alufaa Roomu ẹlẹẹkẹtadin-laadọrin-le-nigba ti o si tun jẹ Adari tuntun ile ijọsin Roman Catholic.

Comments are closed.

button