Olórí ẹgbẹ́ alátakò Ugandan tí ó tún jẹ́ akọrin Bobi Wine ti kéde pé yóò tún díje nínú ìdìbò Ààrẹ ọdún 2026 tí ń bọ̀ yìí, léyìí tí yóò wáyé ní oṣù kìnníí.
Ẹni ọdun mẹtale-logoji ti orukọ rẹ gangan njẹ Robert Kyagulanyi, yoo koju Aarẹ to ti wa lori oye fun ọjọ pipẹ Yoweri Museveni, ti o n beere fun a ti tun dije ibo ni ọgọrin ọdun.
Wine ti kọkọ dije ni ọdun 2021, ti o si ṣe ipo keji, ṣugbọn ti o kọ esi naa, pe o ni eru ninu, kiko iwe idibo ti kii ṣe tawọn oludibo sinu apoti ibo, ati iwa ipa si awọn alatilẹyin rẹ.
Awọn oṣiṣẹ ijọba si sọ pe ohun ti o sọ ko ri bẹ, Wine wa sọ pe idibo naa yoo jẹ “anfaani lati koju” lati fi idi ti o fi pe iṣakoso rẹ kun fun iwa ibajẹ ati aiṣedeede, ati lati ta awọn ọmọ Uganda ji ki wọn o dide fun ominira ara wọn.
O tun wa bẹnu atẹ lu bi awọn ijọba Alawọ funfun ko ṣe sọrọ lori bi ko ṣe si ominira fun ẹtọ ọmọ niyan ni Uganda, bi wọn ṣe n fiya jẹ wọn, ati titi awọn alatilẹyin rẹ mọle ni ọna ti ko bofinmu.
Wine ni ti wọn ba yan ohun, awọn nnkan ti ohun yoo kọkọ mu ṣe ni ominira oṣelu, kikoju iwa ibajẹ, ati wiwa wọrọkọ fi sada lori lilo agbara lọna ti ko tọ.