Take a fresh look at your lifestyle.

Adarí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Tinubu padà wálé ní ọjọ́ Ajé

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

94

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu yóò padà sí Nàìjíríà ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kọkàlé-lógún, oṣù kẹrin lẹ́yìn àbẹ̀wò iṣẹ́ sí Yúróópù.

Agbẹnusọ Aarẹ, Bayo Onanuga, ni o kede rẹ wẹrẹ lori ayelujara X, bayii pe “Aarẹ  Bola Tinubu yoo pada si ile lonii.”

Ikede ti agbẹnusọ Aarẹ ṣe yii ni o kẹyin ipade ọlọsẹ meji Aarẹ ati awọn iṣẹ ṣiṣe loke okun.

Aarẹ Tinubu fi Naijiria silẹ ni ọjọ keji, oṣu kẹrin lọ si Paris, orilẹ ede Faranse, fun abẹwo iṣẹ kekere.

A o ranti pe Aarẹ Tinubu  ṣe ipade ipele giga pẹlu agba Oludamọran fun Adulawọ ni orilẹ-ede Amẹrika, Massad Boulos lasiko abẹwo naa.

Ijiroro Aarẹ pẹlu oṣiṣẹ Amẹrika naa da lori atunbọ fidi ajọṣepọ awọn mejeeji mulẹ lati ṣatunṣe lori aabo Ẹkun ati iṣegbelarugẹ idagbasoke ọrọ aje ibiafẹde jakejado Afirika.

 

Comments are closed.

button