Ààrẹ Bola Tinubu ti ṣe ìdárò lẹ́yìn ikú ẹni ọ̀wọ̀, Pope Francis, tí ó sì ṣàpéjúwe rẹ̀ bíi ‘onítẹríba ẹrú ọlọ́run’ àti ‘Agbẹnusọ fún òdodo, àlàáfíà, àti fún aláìní ’.
Ninu alaye kan ti wọn fisita fun gbogbo aye ni ọjọ Aje, Aarẹ Tinubu darapọ mọ ijọ Katoliiki ati Kirisitiẹni lagbaye lati ṣedaro iku Pope ẹlẹẹkẹrindin-laadọrin-le-nigba, ti saa rẹ bẹrẹ ni ọdun 2013, ti o si fi ipa to lami silẹ niawujọ agbaye.
“Agbaye padanu atọnisọna, alagbawi ti o duro ṣinṣin fun ododo, aṣiwaju fun awọn alini lai kaarẹ ọkan,” Aarẹ Tinubu sọ bayii.
O sọ pe; “O sin ile ijọsin ti o si jẹ Adari ile ijọsin titi ti o fi ṣiwọ iṣẹ.”
Ni iranti aṣesilẹ Pope Francis, Aarẹ Tinubu ṣalaye igbẹnusọ rẹ fun awọn alaini, arinrin ajo ati asasaala, ati igbiyanju rẹ lati koju iyipada oju ọjọ ati aidọgba ọrọ aje.
Aarẹ Tinubu ranti ọrọ iṣiti rẹ fun ọdun Ajinde 2025, nibi to to dunnu nigba ti o ri Pope ti o n ṣaarẹ ti n ṣadura ọjọ Aiku Ajinde ti o maa n ṣe.