Aṣojú Ethiopia si Brazil, Leulseged Tadese Abebe, ti sọ pé kí orílẹ̀-èdè òun jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ilé ìfowópamọ́ ìdàgbàsókè tuntun BRICS jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó wà lọ́kàn òun fún ọdún tí a wà yìí.
Abebe ṣalaye ninu ifọrọ wanilẹnuwo pe,wọn ti fi iwe ibeere silẹ.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, leyin ti o ba darapọ mọ NDB, wọn yoo wa doju kọ ohun to wa niwaju wọn, eto ọgbin, Ina, ati ile iṣẹ.
Ni sisọrọ nipa ipa ti Ajọ Iṣọkan Adulawọ ko ninu BRICS, Abebe ṣalaye pe Ethiopia, South Africa, ati Egypt n ṣe igbelarugẹ ifẹ awọn orilẹ-ede naa ninu Afirika nipa ti afikun ati idagbasoke idaduro laarin ẹgbẹ.
Telẹ, Igbakeji Aarẹ NDB Vladimir Kazbekov,sọ nibi ipade pẹlu Ọga agba oludamọran Bangladesh Muhammad Yunus, pe ile ifowopamọ naa ti ṣetan lati kopa ninu awọn iṣẹ akanṣe orilẹ-ede ninu ina mọnamọna, lilọ bibọ, ipese omi, ati amayedẹrun ayarabi aṣa.
Wọn da Ile ifowopamọ idagbasoke tuntun silẹ ni ọdun 2014 lati ṣatilẹyin fun awọn agbekalẹ idagbasoke adebi a fẹ de ni awọn orilẹ-ede BRICS.
Lati igba ti wọn ti da silẹ, ile ifowopamọ naa ti ṣenawo awọn iṣẹ akanṣe pataki ni Gusu Agbaye.