Take a fresh look at your lifestyle.

Hajj 2025: Eko Ṣonígbọ̀wọ́ àyẹ̀wò ìlera fún àwọn tó fẹ́ rìnrìn àjò mímọ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

82

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Eko, Ọ̀gbẹ́ni Babajide Olusola Sanwo-Olu àti igbákejì rẹ̀, Dókítà Kadri Hamzat ti Ṣonígbọ̀wọ́ àyẹ̀wò ìlera pataki fún àwọn tó fẹ́ rìnrìn àjò mímọ́ lọ sí orílẹ̀ èdè Saudi Arabia láti ìpínlẹ̀ Eko.

Igbesẹ yii waye lati mu ọrọ rẹ to sọ wa si imuṣẹ pe gbogbo awọn to ba fẹ rin irin ajo mimọ naa lati ipinlẹ naa gbọdọ ni ilera to dangajia.

Nigba ti o n sọrọ nibi ifilọlẹ eto ilera naa ni olu ile iṣẹ ijọba ibilẹ Badagry, Ajarah, Kọmiṣọna, Ile iṣẹ ti n riri ọrọ orilẹ-ede, ti o tun jẹ Amir-ul- Hajj, Ọgbẹni Ibrahim Layode, sọ pe ipinlẹ Eko mu iwa lalaafia awọn arinrin ajo lọkunkun dun, ti o si ni ipinnu lati pese ayẹwo yii ni lati ranwọn lọwọ lori inawo lẹyin ti wọn ti san owo ribiribi ti o fẹẹ to miliọnu mẹsan Naira fun irin ajo naa bi gbogbo nnkan ṣe le to lorilẹ-ede.

O wa ṣalaye pe esi yoo gbee jade ti wọn ba yege ayẹwo naa lẹyin ti wọn ba ti gba itọ ati ẹjẹ, ti yoo si tun ran wọn lọwọ lori iṣetọju wọn lasiko igba ti wọn yoo fi wa ni ilẹ mimọ naa.

Comments are closed.

button