Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ UNICEF Pèsè Mílíọ̀nù Mẹ́ẹ̀dógún Owó Ìrànwọ́ Fún Ìpínlẹ̀ Kaduna,Kebbi Àti Bauchi

172

Àjọ UNICEF ti pèsè Mílíọ̀nù Mẹ́ẹ̀dógún Owó Ìrànwọ́ fún Ipinlẹ Kaduna,Kebbi, àti Bauchi ní ọnà láti ró ijọba àti agbègbè lágbára fún ìpèsè ohun ètò tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀, ètọ́ ọmọnìyàn àti ohun ètò ìlera.

Nígbàtí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ètò Ọlọ́jọ́ Méjì nípa ìrónilágbára ní Kaduna, akọ́sẹ́mọ́sẹ́ ètò ìlera, Dókítà Chelsea Fatima, ní ilé iṣẹ àjọ UNICEF ní Abuja fihàn pé, ìpèsè ìrànwọ́ náà wá láti ọdọ – Global Affairs Canada, ati pé yóò sì wà fún ọdún, màrùn ún fún àwọn ọmọbìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, obìnrin tọ́jọ́ orí wọn ń bímọ àti àwọn ọmọdé ti wọn kò kọjá ọdún márùn ún ọjọ́ orí.

Dókítà Aisha Abubakar Sadiq  to6 jẹ́ akọ̀wé àgbà, Mínísirì ìlera ipinlẹ Kaduna fi ìdùnnú rẹ̀ hàn fún àsìkò ìpèsè ìrànwọ́ náà pé Global Affairs Canada fẹ́ ètò ìlera tó péye fún àwọn obìnrin, ọdọmọbìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà àti àwọn èwe.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
.

Comments are closed.

button