Gómìnà ìpínlẹ̀ Abia Alex Otti ti pé àkíyèsí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Abia latari bi wọn ṣe n se ìtọjú ojú wọn ní ọna ti ko tana.
Gómìnà ni èyìn leè ṣe òkùnfà kí ojú náà fò pátápátá Lai sí àtúnṣe.
Ó ṣe ìkìlọ náà ni ọjọ́rú lásìkò ìfilọ́lẹ̀ NNPC àti ètò ìse abe ọfẹ fún àwọn ẹgbẹrun kan ènìyàn ni ilé ìwòsan Ábíá Specialist Diagnostic Center, ni Umuahia.
Kọmísọ́nà fún ètò ìlera ló sojú Gómìnà níbi ayẹyẹ náà, Ọ̀mọ̀wé Enoch Uche.
Ó ní gbígbà ìtọjú lọ́wọ́ àwọn ti ko mó ipá iṣé ìtọjú ojú leè mu àkóbá nlá bá ilera ojú.
Ó rọ àwọn ènìyàn láti rí wí pé wọn gbà ìtọjú láti owó ìjọba àti ilé ìwòsan ìjọba.