Gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra Fi Orí Ọ̀nà Àbálọ Sí Pápákọ̀ Òfúrufú Sọ Orúkọ Gómìnà Tẹ́lẹ̀rí Láti Bu Ọlá Fún
Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra, ọjọgbọn, Chukwuma Soludo
ti sọ ọ̀nà tó lọ sí pápákọ̀ òfurufú Chinua Achebe ní ìlú Umueri ní- “Willie Obiano Boulevard,” láti fi bù ọlá fun Gómìnà àná -Chief Willie Obiano.

Ìkéde yìí wáyé níbi ayẹyẹ ìsíde ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé pápákọ̀ òfurufú ní ọjọ́ Ajé.

Gómìnà Soludo lu iṣẹ́ rere Obiano lọ́gọ ẹnu iṣẹ́ takuntakun ọdún méjọ rẹ, pàápàjùlọ akitiyan rẹ láti ri pé isẹ́ Papakọ̀ òfurufú àti gbigbe International Convention Center (ICC) wá sí ìlú Awka di ṣíṣe.

Soludo sọ pé gbogbo àwọn agbègbè ti wọn ti gbàgbé bí Àríwá ní àwọn yóò ti bẹrẹ àkànṣe iṣẹ́, agbègbè bíi Okpoko àti Olumbanasaa.
”Àríwá kò ní àwọn ohun èèlò àmúyẹ, wọn kò ní nǹkan kan bi wọn ṣe ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tó, ìdí nìyí tí a óò fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ níbí yìí”, ó sọ èyí.
Àwọn tó wá síbi ayẹyẹ náà láti ri igbákejì Gómìnà, Onyekachukwu Ibezim, Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Anambra, ọ̀gbẹ́ni Somtochukwu Udeze pẹ̀lú àwọn lọ́balọ́ba àti asojú ti ètò idajọ́.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san