Omi àgbàrá Òjò ti pa Mẹ́tàlélọ́gbọ̀n olùgbé, ó sì tún gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lọ ni Kinshasa ti ṣe Olú ìlú Congo.
Bí Mínísítà òde orílẹ̀-èdè ṣe sọ, àwọn tó lùgbàdí ọ̀ràn náà ni àgbàrá Òjò àrọ̀rọ̀rọ̀dá sekúpa, tó sì gbélé lọ ti àwọn kan sì wà lábẹ́ omi.
” Ó ṣeéṣe kí oye àwọn ènìyàn to kú lọ sókè síi, o tó bíi àádọta ènìyàn to wà nílé ìwòsàn báyìí, àwọn adóòlà ẹ̀mi sì ní gbìyànjú àti wà àwọn ènìyàn to nù kiri ti àgbàrá ti gé ọnà wọn danu”, o sọ eyi.
Gómìnà ìlú nlá náà, Daniel Lubaki sọ pé ọpọ ènìyàn tó kú jẹ́ látàrí ilé ti wọn kò kọ́ dáradára, tàbí ilé ti wọn kò lo èròjà ìkọ́lé tó bòfin mú tàbí kọ́lé láì gba ìyọ̀nda ìkọ́lé, ilé tó súnmọ́ odò.
Awọn ti kò nílé lórí mọ ní wọn fún wọn làaye ní pápá iṣere, ” Mínísirì sọ eyi.
Àmì ti jeyo báyìí pé ìkún omi àgbàrá náà ti ń fà, ọnà sì Papakọ̀ òfurufú Kinshasa ti di ṣíṣí báyìí.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san