Take a fresh look at your lifestyle.

Ukachukwu yege láti kópa nínú ìbò Gómìnà APC fún Anambra

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

84

Ọmọ Ọba Nicholas Ukachukwu ti jáwé olúborí bíl olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) fún ìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra tí ń bọ̀ lọ́nà ní oṣù kọkànlá ọdún 2025.

Ukachukwu jawe olubori nigba ti o yege ninu ibo abẹle ti o waye ni Gbongan Dora Akunyili fun idagbasoke awọn obinrin ni Awka, leyi ti o bẹrẹ ni aajin ọjọ Abamẹta titi di aarọ kutu ọjọ Aiku.

Iyege ti o foju han gbangba, Ukachukwu ni ibo ẹgbẹrun kan –le-ni-aarun –din-lẹgbaata, leyi ti o ju oludije pẹlu rẹ, Valentine Ozigbo lọ, leyi ti o ni ibo mẹtadin-laadọrin. Awọn oludije to ku ni Johnbosco Onunkwo, ti o ni ibo mẹrindin-lọgbọn, ati Edozie Madu, ti o rọju ni ibo mẹjọ pere.Ibo mẹrindin-lọgbọn ko si dara.

Ọgbẹni Bassey Otu, Gomina ipinlẹ Cross River ti o tun jẹ Alaga ẹgbẹ eto idibo APC, ti o kede Ukachukwu bii oludije ti gbogbo ẹgbẹ yan, tọka si bi “Olori APC ní ipinlẹ Anambra.” 

BPẹlu agbara ni ikapa mi bii ọga agba alabojuto, mo kede rẹ bii ẹni ti o jawe olubori ninu ibo abẹle APC ipinlẹ Anambra,”  Gomina Otu sọ bayii.

.

Comments are closed.

button