Mínísítà Nàìjíríà fún Olú Ìlú (FCT), Ọ̀gbẹ́ni Nyesom Wike, ti ṣèdárò pẹ̀lú Gómìnà Ìpínlẹ̀ Benue nígbà kan rí, Samuel Ortom, lórí ikú ọmọkùnrin àbúrò rẹ̀, Ọgbẹni Bernard Tyozenda Ortom.
Ninu alaye kan lati ọdọ oluranlọwọ agba pataki fun Minisita lori iba ara ilu sọrọ ati Ayelujara, Lere Olayinka, ni ọjọ Iṣẹgun, Minisita Olu Ilu, ṣapejuwe iku Bernard Tyozenda Ortom bi eyi ti o dunni, ti o si gbadura ki ọlọrun tẹ si afẹfẹ rere.
O wa rọ Gomina Ortom ati gbogbo ẹbi Ortom Adorogo ti ijọba ibilẹ Guma Ipinlẹ Benue lati mọkan ki wọn o si gba fọlọrun, oun nii funni ti sii gbaa.
The Minister said, “Iroyin iku Ọgbẹni Bernard Tyozenda Ortom Nicholas bani lojiji, mo mọ bi ipadanu naa yoo ṣe ri lọkan ọrẹ mi, Dokita Samuel Ortom bayi.
“Ṣugbọn, bi iku naa ṣe bani lojiji ti o si dunni, mo rọ ẹ pe ki a gba fun ọlọrun, ti o ṣe iku ni ohun ti ẹnikan ko le mujẹ.
“Ni orukọ ẹbi mi, awọn ọrẹ, ati alabaṣepọ, mo kẹdun pelu rẹ lori iṣẹlẹ aburu yii. Adura mi ni pe ki ọlọrun, ninu aanu rẹ, ko rọ ẹ ati gbogbo ẹbi Ortom Adorogo loju fun ipadanu yii.”