Onímọ̀ nípa Àìsàn ọpọlọ Dọ́kítà Zubairu Umar ti rọ àwọn ènìyàn ni àgbègbè láti ni àkíyèsí àwọn ènìyàn nípa àìsàn ọpọlọ ni agbègbè fún ìtọ́jú lásìkò.
Umar to jẹ igbákejì ilé ìwòsan ìjọba àpapọ̀ to n mójú ètò ọpọlọ ni ìpínlẹ̀ Kware ni ìpínlẹ̀ Sokoto ló sọ èyí di mímọ̀ lásìkò ìpàdé pẹlu àwọn lọ́balọ́ba ni ọjọ́ ìsimi.
Umar sàlàyé wí pé o ṣe pàtàkì láti ma ṣe akiyesi ará wa pàápàá jùlọ àwọn ti a Jo n gbé pọ láti rí wí pé wọn wá nínú ìlera pipe lati inu ọpọlọ.
Ó ni yò jọ ìjọba, àwọn tọrọ kàn, ẹgbẹ́ àti àwọn ènìyàn agbègbè sílẹ̀.
Ó ní íwáàdí fi hàn wí pé méjì láàrin àwọn ènìyàn mẹrin ni o ni idojukọ àìsàn ọpọlọ, látàrí ìrònú, wàhálà, ìrora,iporuru ọkan àti ìbẹrù.
Ó ní àwọn miran nípa, ọ̀gùn olóró, ajogún ba àìsàn láti ọdọ àwọn òbí, àìsí ìtọjú láti ìgbà èwe náà tù le mú kí àìsàn gbilẹ lara ènìyàn.
Ó tèsíwájú wí pé kí wọn tètè rí Dọ́kítà fún ìtọ́jú tó péye bí wọn bá ko firi nkán ki ọ to bo sí nkan míràn ti agbára o le ká, ki wọn si sá fún ìtọjú ìbílẹ̀ ti o tubọ fàá àní ìwòsàn ni kíákíá.