Mínísítà rọ àwọn akọ̀ròyìn lórí ìròyìn déédé àti ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ilé iṣẹ́ Nàìjíríà tí ń mójútó ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìpele kejì ìbáraenisọ̀rọ̀ ilé iṣé náà fún ọdún 2025, tí ó sì rọ àwọn akọ̀ròyìn láti fi ìròyìn déédé, ìwọ̀ntún wọ̀nsì, àti ìsòdodo síwájú nínú ìkọ̀ròyìn wọn.
Ninu ọrọ ikini rẹ, Minisita fun eto ibaraenisọrọ ati Ifihan , Mohammed Idris, wa gboriyin fun awọn akọroyin bi wọn ṣe n gbe gbogbo eto ijọba si etigbọ awọn eniyan, ti o si tun n gba wọn niyanju lati tẹsiwaju lori isododo ati iṣe deede ninu iroyin wọn.
Gẹgẹ bi Minisita fun Eto ibaraẹnisọrọ ṣe sọ, eto ifitoni leti yi jẹ pẹpẹ lati ṣe afihan awọn aṣeyọri ijọba Tinubu jake jado awọn ipele ọrọ aje.
O fi kun un pe agbekalẹ naa ṣafihan ifọkansi ijọba naa lori ifihan sita gbangba, ijiṣẹ, ati ibaraẹnisọrọ to muna doko pẹlu awọn eniyan Naijiria.
Idris wa mu dani loju pe ijọba yoo pese gbigbe awọn eto ibaraẹnisọrọ naa safẹfẹ jake jado pẹpẹ ipolongo ti o ti wa tẹlẹ ati ti ayelujara lati ṣagbelarugẹ ijiṣẹ ati ijabọ lati ọdọ awọn eniyan.
Awọn ipele ibaraẹnisọrọ Minisita naa yoo tẹ siwaju pẹlu awọn oṣiṣẹ ijọba pataki, ti yoo maa fi iroyin eto idagbasoke ijọba ni oniruuru abala to awọn eniyan leti loore koore.Minisita fun eto idagbasoke awọn ohun ọsin,Idi Mukhtar ati ti Idagbasoke Agbegbe, Ọgbẹni Abubakar Momoh, lọ kọkọ ṣaaju.