Ijóba Ìpínlẹ̀ Kwara ti fi dá àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú pé òun yoo se ise òun bí iṣẹ́ nípa líla àwọn ènìyàn lọ́yẹ̀ ewu tó wà ninú ki àwọn kan máa se ìgbọ̀nsẹ̀ síta gbangba káàkiri.
Nígbàtí ó ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ọ̀gá àgbà Ilé iṣẹ Kwara State Rural Water Sanitation Agency (RUWASA), ọ̀gbẹ́ni Olorunfemi Oladipo sọ pé kí àwọn ènìyàn fi òpin si Ìgbọ̀nsẹ̀ Ṣíṣe síta gbangba káàkiri ní Ìpínlè náà. Pé wọn yóò gbé àjọ olùbẹ̀wò kan síta ní ìjoba ìpínlẹ̀ àti ìbílẹ̀ ti yóò bẹ̀rẹ̀ si ní yẹlé wò. Ó kéré tán Ilé kọ̀ọ̀kan nílàti ní Ṣálángá.
Nígbàtí ó ń bá àwọn èniyàn sọrọ ní tirẹ̀, olórí ẹ̀ka ètò ìmọ́tótó, ọ̀gbẹ́ni Abdulazeez Rufai rán àwọn ènìyàn létí pé, ìmọ́tótó ni ó súnmọ́ ìwà bí Ọlọ́run, pé kí àwọn ènìyàn máa wà ni ìmọ́tótó nígbà gbogbo fún ànfààní ara wọn.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san