Ètò àgbékalẹ̀ owó Àádọ̀jọ Bílíọ̀nù Náírà fún àkànṣe ètò ìpèsè Reluwé ní ìpínlẹ̀ Kano láti ọwọ́ ààrẹ Bola Tinubu yóò mú kí ọrọ̀ okòwò, ajé rúgọ́gọ́
síi ní ìlú Kano àti gbogbo agbègbè Àríwá Nàìjíríà.
Ọgá àgbà àjọ Hadejia-Jama’are River Basin Development Authority (HJRBDA), Alhaji Rabi’u Bichi ló sọ èyí nínú àkọsílẹ kàn ni ìpínlẹ̀ Kano. Ó gbósùbà ràbàndẹ̀ fún ààrẹ fún ìgbésẹ̀ yìí.
Ó fi kun pé, ìjọba ààrẹ Tinubu ní àfojúsùn ìpèsè ohun amáyédẹrùn fún mùtúmùwà bí wọ́n ti se fọwọ́ sí nínú ìṣúná ọdún 2025 fún àtúnṣe ọ̀rọ̀ nípa ètò ìlera abbl.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san