Olùgbadé ìdíje ni ìgbà méje, ikọ̀ Flying Eagles yóò koju ikọ̀ Egypt, South Africa àti Morocco ní ipele ibẹrẹ idije ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ ti ọjọ́ orí wọn kò kọjá ogún odún-U-20 Africa Cup of Nations (AFCON), ti yóò bẹ̀ryẹ ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹrin títí di ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kàrùn ún ní orílẹ̀-èdè Cote d’Ivoire.
Ikọ̀ Flying Eagles gbo ewúro sójú ikọ̀ Egypt tó gbàlejò ìdíje pẹ̀lú ayò kan sí odò (1-0) ni ipele ìbẹ̀rẹ̀ ni ìdíje tó kojá, ikọ̀ Egypt níláti túra mú báyìí. Nàìjíríà se ipò kẹta ní ọdún méjì séhìn ní orílẹ̀-èdè Egypt nínú ìdíje tó kojá.
Ìsòrí tó le koko bí ojú ẹja ni ìsòrí ti ikọ̀ Nàìjíríà wà bí agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ rí orílẹ̀-èdè Málì, Adama Coulibaly,se sọ níbi ìyí koto sí ìsòrí ìsòrí ni ọjọ́ ojọ́bọ̀. ” Ìsòrí ti ikọ̀
Nigeria, Egypt, South Africa àti Morocco wà ló lágbára jù.”.
Olùgbàlejò ìdíje ,Cote d’Ivoire yóò máa kojú DR Congo, Ghana, Tanzania pẹ̀lú orílẹ̀-èdè kan ti kò ti farahàn ní àgbègbè
Central Africa zone ní ìsòrí A.
Orílẹ̀-èdè tí ife ẹ̀yẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀, Senegal
yóò máa kojú Zambia, Kenya àti Sierra Leone ní ìsòrí C.
Ikọ̀ méjì tó se dáradára jùlọ ní ìsòrí kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú onípòkẹta méjì tó dára jù ni gbogbo ìsòrí yóò ni ànfààní láti wọ ipele tó kángun sí àsekágbá.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san