Take a fresh look at your lifestyle.

Olùdarí Aṣòfin Èkó Rọ Àwọn Agbóhùnsáfẹ̀fẹ́ Orí Rédíò Láti Máa La Àwọn Ará Ìlú Lọ́yẹ̀ Nípa Ọ̀rọ̀ Àyípadà Ojú-ọjọ́

119

 

Olùdarí Ilé Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó, Aṣòfin Mojísọ́lá Lasbat Meranda ti rọ àwọn Agbóhùnsáfẹ̀fẹ́ orí rédíò láti tẹ̀ síwájú nínú akitiyan wọn láti máa la àwọn ará ìlú lọ́yẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ àyípadà ojú-ọjọ́

Nígbà tí ó ń kí àwọn òṣìṣẹ̀ ilé-iṣẹ́ Agbóhùnsáfẹ̀fẹ́ rédíò kú oríire Àyájọ́ Rédíò Lágbàáyé tí ọdún 2025 yìí, Olùdarí náà tẹnu mọ́ iṣẹ́ ribiribi tí rédíò ti ṣe fún ẹ̀mí Ìṣọ̀kan láàrin àwọn ẹ̀yà gbogbo, dáàbò bo òmìnira àwọn ará ìlú nípa fífún wọn láǹfààní láti sọ èrò ọkàn wọn, tí ó ṣí fún olúkúlùkù láǹfààní sí ìròyìn lóríṣiríṣi.

Aṣòfin Meranda wòye pé, àkòrí Àyájọ́ Rédíò ọdún yìí dàlé Ipa Rédíò nínú Ọ̀rọ̀ Àyípadà Ojú-ọjọ́, yóò lé jẹ́ kí àwọn ilé-iṣẹ́ rédíò jí gìrì sí àkóónú yìí. Ó ní:

“Ẹ̀rọ Agbóhùnsáfẹ̀fẹ́ rédíò jẹ́ ẹ̀rọ alátagbà ìròyìn tó ṣe pàtàkì fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́, ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀, àti ìlánilọ́yẹ̀ pàápàá ní àsìkò pàjàwìrì. Ní Ìpínlẹ̀ Èkó níbí a mọ rírì ẹ̀rọ náà fún gbígbé ìròyìn pàtàkì lórí ìlánilọ́yẹ̀ nípa àyípadà ojú-ọjọ́un àti ìpalára rẹ̀ fún àwùjọ, ìlera àti Ọjọ́ iwájú wa”

“Gẹ́gẹ́ bí Olùdarí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó, mo ṣe tán láti ṣàtìlẹ́yìn fún ìlánilọ́yẹ̀ báyìí nípa àyíká àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìdàgbàsókè ìlú, pàápàá nípa fífi ọwọ́ sowópọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ ìròyìn. Ẹ jẹ́ kí á gbá rùkù ti agbára ẹ̀rọ Agbóhùnsáfẹ̀fẹ́ rédíò láti dáàbò bo àwùjọ wa”

Lánre Lágada-Àbáyọ̀mí

Comments are closed.

button