Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Gúnlẹ̀ Sí Orílẹ̀-èdè Ethiopia Fún Àpérò Ilẹ̀ Adúláwọ̀

61

Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Bọla Ahmed Tinubu ti gúnlẹ̀ sí ìlú Addis Ababa, Ethiopia ní alẹ́ Ọjọ́bọ̀ láti kópa nínú ìpàdé àpérò ilẹ̀ adúláwọ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejìdínlógójì irú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ èyí ti yóò dá lé lórí ìlọsíwájú ilẹ̀ Afirika lápapọ̀

 

Lára àwọn tí ó kí ààrẹ Tinubu káàbọ̀ ní pápákọ̀ òfurufú ni Eshetu Legesse, tí ó jẹ́ igbákejì alákòsóo iṣẹ́ ààrẹ Orílẹ̀-èdè Ethiopia, mínísítà fún Ọ̀rọ̀ Ilẹ̀ Òkèèrè ti Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Àm̀básádọ̀ Yusu Tuggar àti ojúgbà rẹ ti Orílẹ̀-èdè Ethiopia, Nasir Aminu

 

Ní kété ti Aarẹ Tinubu gúnlẹ̀, wọ́n sàlàyé àfojúsùn ìpàdé àpérò náà àti àwọn àseyorí ti Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ṣe gẹ́gẹ́ bi adarí ilẹ̀ Afirika. Ìrètí wà pé Aarẹ Tinubu yóò bá àwọn akẹgbẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ níbi tí wọn yóò ti wá ojútùú sí ìsòro àìrajaja ètò ààbò àti fífi òpin sí aáwọ̀ tí ó  wà láàrin àwọn Orílẹ̀-èdè kan sí ìkejì ní ilẹ̀ adúláwọ̀

Comments are closed.

button