Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Yìn Àjọ IFC Fún Owó Ìdókòwò Àádọ́ta Mílíọ̀nù Dọ́là

Lekan Orenuga

312

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tí gbóríyìn fún àjọ tó ń rí sí ètò ìnáwó àgbáyé (IFC) fún owó ìdókòwò àádọ́ta mílíọ̀nù dọ́là ní àgbègbè Ọ̀fẹ́ ní Èkó.

‎ Iyìn yìí wá latari ìgbàgbọ́ tí àjọ náà ní nínú ètò ọrọ àjé Nàìjíríà, Ààrẹ Tinubu nínú ọrọ kán tó fí ọwọ́ sí nípasẹ Olùdámọ̀ràn pàtàkì rẹ̀ lórí Àlàyé àti Ìlànà, Ọ̀gbẹ́ni Bayo Onanuga, ṣàpèjúwe ìdókòwò náà gẹ́gẹ́bí ẹrí sí igbẹkẹle tí àwọn ilé-iṣẹ́ ìṣòwò àgbáyé ní nínú ìtọ́sọ́nà ètò-ọrọ àjé Nàìjíríà lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀.

‎ Ààrẹ náà, tó yìn ‘Tolaram initiative’, èyítí o ṣé àtìlẹ́yìn fún ìdàgbàsókè àti imugboroosi ọjà tí àgbègbè ìjìnlẹ̀ ibùdó ọkọ òkun àkọkọ́ tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó tẹnu mọ́ pé irú àwọn àjọṣepọ̀ bẹẹ ní yóò mú orílẹ̀-èdè náà àti ìdàgbàsókè àwọn ilé-iṣẹ́.

‎ Ààrẹ Tinubu tún gbóríyìn fún IFC, o sọ pé àjọ ètò ìṣúná owó káríayé kì yóó mú ìlọsíwájú bá àwọn ilé-iṣẹ́ Nàìjíríà nìkan, ṣùgbọ́n yóò ṣàfihàn igbẹkẹle àwọn olúdókòwò káríayé nínú àwọn ètò ìmúlò ọrọ àjé tí ìjọba rẹ̀.

Comments are closed.

button