Ìjọba Nàìjíríà túnbọ̀ fìdí ìpinnu rẹ̀ lórí ìrìnàjò lọ sílùú mìíràn lọ́nà òfin múlẹ̀
Eyitayó Fauziat Oyetunji
Ìjọba Nàìjíríà ti túnbọ̀ fìdí ìpinnu rẹ̀ láti ri pé àwọn ìrìnàjò láti Nàìjíríà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn wáyé lọ́nà tó bòfin mu múlẹ̀, tí ó sì ṣàlàyé àǹfààní ọrọ̀ ajé àti ìdábòbò àwọn arìnrìn àjò.
Minisita eto Iṣẹ ati Igbanisiṣẹ ní Naijiria, Muhammad Maigari Dingyadi, sọ eyi di mimọ lasiko ti o n gbalejo aṣoju kan lati Ile Iṣẹ Germany IHK Giessen-Friedberg ti n mojuto Eto kata kara ati ile iṣẹ n pese nkan ni Abuja.
Alhaji Lai Mohammed, ti o figba kan jẹ Minisita fun eto ibaraẹnisọrọ ati Aṣa, ni o ṣe alatọna abẹwo naa, ni ẹni ti o si jẹ Oluṣakoso keji lori ajọṣepọ ara ilu fun ile iṣẹ Bruit Costaud.
Ijiroro yii da lori ṣiṣe irin ajo Iṣẹ lọna tobofin mu ati idagbasoke eto idanilẹkọ iṣẹ ọwọ fun ilọsiwaju ọrọ aje.
Dingyadi wa fi da aṣoju naa loju pe ijọba ti ṣetan lati fọwọsowọpọ lati ri pe wọn jọ ṣaṣeyọri lori ọrọ naa, paapaa julọ ṣatunṣe ọna irinrin ajo ati idagbasoke iṣẹ ọwọ.
Minisita wa tun ṣalaye pataki idanilẹkọ iṣẹ ọwọ lati ro awọn ọmọ Naijiria lagbara pẹlu iṣẹ ọwọ to jọju, ti kii ṣe pe yoo ran wọn lọwọ lati ri iṣẹ ni oke okun nikan ṣugbọn bi ko ṣe pe yoo tun ko ipa idagbasoke fun orilẹ-ede nigba ti wọn ba pada silu.
Alhaji Lai Mohammed wa gboriyin fun aṣoju German naa lori akitiyan wọn ti n lọ lọwọ lati ṣafidimulẹ ajọṣepọ eto ọrọ aje to wa laarin awọn orilẹ-ede mejeeji naa.