Ààrẹ Tinubu ṣàjọyọ̀ pẹ̀lú ògbóhùntarìjgì òṣèré Nkem Owoh ní ààdọ́rin ọdún
Eyitayó Fauziat Oyetunji
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti kí ògbóhùntarìjgì òṣèré Nollywood, apanilẹ́ẹ́rín,akọrin tí ó tún jẹ́ olukọ̀ọ orin, Ọ̀gbẹ́ni Nkem Owoh, MON, bí ó ṣe ń ṣe ọjọ́ ìbí ààdọ́rin ọdún rẹ̀.
Lori ajọyọ naa, aarẹ Tinubu gboriyin fun ipa ti Owoh ko ninu ile iṣẹ idanilaraya Naijiria ati aṣe silẹ rẹ bii ọkan ninu ẹni ti awọn eniyan nifẹ si juloọ.
Ninu ifiranṣẹ kan ti Bayo Onanuga, Oludamọran pataki lori ibaraẹnisọrọ ati Ọgbọn,si aarẹ, sọ pe Nkem Owoh fi gbogbo ara si isọtan ti o jẹ idanilaraya fun miliọnu awọn eniyan leyi ti o ṣafihan aṣa to dara si agbaye.
“Osuofia” ti awọn ololufẹ rẹ fẹran– orukọ ti o mọ lori nibi ipa ti o ko ninu ere apani lẹrin ti o milẹ titi ‘Ikuku apa kinni ati ikeji ’ ati ‘Osuofia ni London’ – Nkem Owoh ti gbin ara rẹ si ọkan awọn oluworan lati igba pipẹ pẹlu ọgbọn ati pipa oriṣiriṣi itu.
Gẹgẹ bii asiwaju ni Nollywood ati ere ori mohun maworan, o ti gba awọn ọpọlọpọ agboriyin, bii Africa Movie Academy Award (AMAA) fun oṣere ti o dara julọ ninu ipa pataki ti o ko ninu ere‘Stronger Than Pain,’ ni 2008, leyi ti omu jẹ opo mulero ni c Nollywood.