Àjọ US Postal Service (USPS) ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti so gbígba ẹrù láti Ilẹ̀ China àti Hong Kong rọ̀ fún ìgbà kan ná.
Lẹ́tà gbígbà wọlé kòsí ní abẹ́ òté náà bi àkọsílẹ ti sọ láti orí ìtàkùn kálé káko ilé Iṣẹ́ wọn.
Àjọ USPS kò sọ ìdí tí wọ́n fi se bẹ́ẹ̀ sùgbọ́n ìgbésẹ̀ yìí wáyé lẹ́yìn tí ààrẹ Donald Trump gbé ẹ̀kúnwó ìdámẹ̀wá nínú ọgọ́rùn ún lé gbogbo ẹrù ọjà tó ńwọlé láti orílẹ̀-èdè China sí Amẹ́ríkà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san