Bísọ́ọ̀bù àgbà ti ìlú Cape Town se ìpàdé ní ọjọ́ ìṣẹ́gun lẹ́yìn àgbéyẹ̀wò tí wọ́n rí pé àwọn ìgbìmọ̀ mọ̀ pé ìjọ Anglican ni South Africa kùnà láti sọ fún àwọn ìjọ míràn ewu tó lágbára tó wà níbẹ látàrí ìlòkulò ọmọdé lọ́wọ́ ọ̀gbẹ́ni John Smyth.
“Mo gba ìwádìí àwọn igbimọ̀ wọlé. Lóòótọ́, ni àkókò Smyth ni ìlú Cape Town, àwọn ènìyàn Ọlọrun mọ bi wọn se ń lo ọmọde ni ìlòkulò, èmi àti Díósìsì tọrọ àforíjì lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọmọ ìjọ àti gbogbo olùgbé pé lótítọ́ a kò dènà ewu tó wà níbẹ̀ ,” Thabo Makgoba sọ èyí.
Bí Makgoba se sọ, àgbéyẹ̀wò ìgbìmọ̀ sọ gbogbo ìgbésẹ̀ to kọjá ti ìjọ ni South Africa gbé pèlú ìròyìn nípa ìlòkulò èwe ti ọ̀gbẹ́ni Smyth ni ọdún 1981 àti 1982 ní U.K àti ní ọdún 1990 ni Zimbabwe, tí wọ́n gbà láti Díósìsì Ely ní ọdún 2013.
Makgoba sọ pé, títí di ìsisìyí wọn kò rí ìròyìn kánkán gbà nípa ìlòkulò ní ilé ìjọsìn orílẹ̀-èdè South Africa.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san