Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kaduna Fẹ́ Mójútó Ọ̀gbìn Èso Gírèpù

135

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kaduna, Uba Sani ti fi dá àwọn àgbẹ̀ eléso Gírèpù lójú pé ìjọba òhun yóò pèsè èso ti wọn yóò gbìn, ẹ̀rọ fún oko Gírèpù, ẹ̀ko àti àtìlẹ́yìn to gbúnpon fún wọn fún ìmúgbóòrò ọ̀gbìn náà.

Gómìnà se ìlérí yìí nígbàtí ó se ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú àjọ Grapes Producers Processor’s And Marketers Association of Nigeria (NGRAPPMAN), ti alaga ìjọba àpapọ̀ wọn, Alhaji Abdullahi Dalhatu to siwaju rẹ ni ìlú Kaduna.

Ó ṣèlérí pé, ìjọba ibilẹ Kudan yóò di ìlú- mọ̀ọ́ká nínú ọ̀gbìn Gírèpù jakejado orilẹ-ede yìí, ìpínlẹ̀ Kaduna yóò sí tun ti wọ́n lẹ́yìn.

Gómìnà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ àjọ náà nípa gbígbé ipinlẹ Kaduna ga lati jẹ ipinlẹ to n pèsè ọpọ yanturu Gírèpù, o fi da wọn loju pé àwọn yóò fi ọwọ sowọ́ pọ pẹlú ẹ̀ka náà.

Alága àjọ náà gbóríyìn fún Gómìnà fún ìfẹ́ rẹ̀ ṣí ètò ọ̀gbìn náà àti gbogbo ètò rere àti ìlànà rẹ̀ fún ìtẹ̀síwájú ọ̀rọ̀ nípa ètò ọ̀gbìn láti lé ìṣẹ́ òhun òsì kúrò ní ìpínlẹ̀ náà àti kí ọrọ̀ ajé leè máa tẹ̀ síwájú.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button