Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Lọ Fún Ìpàdé Àpérò Ní Orílẹ̀-èdè Tanzania

119

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti balẹ̀ gùdẹ̀ sí Dares Salaam orílẹ̀-èdè Tanzania láti kópa níbi Ìpàdé apero ti wón pé ni “Mission 300 Africa Energy Summit” ti yóò bẹ̀rẹ̀ ní òní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n.

Ààrẹ dé ni aago mẹ́jọ kọjá ogún iṣẹ́jú alẹ́ ti Nàìjíríà (8:20 p.m. Nigerian time), Mínísítà ilẹ òkèèrè ile Tanzania, Àmbásédọ̀ Mahmoud Thabit Kombo àti ti Nàìjíríà, Àmbásédọ̀ Salisu Suleiman, si lọ gbàá lálejò.

Ìpàdé Ọlọ́jọ́ méjì náà ni ìjọba Tanzania, àjọ African Union, African Development Bank Group, àti World Bank Group se agbáterù rẹ̀.

Àmbásédọ̀ Bianca Odumegwu-Ojukwu, Ogbeni Adebayo Adelabu, Mínísítà kékeré fún ilẹ̀ òkèèrè , Mínísítà agbára, ọgbẹ́ni Olu Verheijen, oludamọran pàtàkì sí ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ nípa agbára abbl. ló bá ààrẹ Tinubu kọ̀wọ́ rìn .

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button