Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì Ààrẹ Shettima kẹ́dùn pẹ̀lú Gómìnà Ìpínlẹ̀ Jigawa lórí Àjálù méjì tó ṣẹlẹ̀ si

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

143

Ààrẹ Bọla Tinubu ti yan àwọn asojú kan tí Igbákejì Ààrẹ Kashim Shettima ṣadarí, láti ṣe àbẹ̀wò ìkẹ́dùn sí Gómìnà àti àwọn ènìyàn Jigawa lórí ikú ìyá àti ọmọkùnrin  Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Alhaji Umar Namadi.

Laarin wakati mẹrinle-logun ti iya rẹ, Hajiya Mariam jẹpe ọlọrun ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣu kejila, o tun ṣe ipadanu ẹmi ọmọkunrin rẹ ti o dagba julọ, Abdulwahab ní ọjọ kẹrinle-logun oṣu kejila.

Igbákejì Ààrẹ kọwọrin pẹlu Gomina ipinlẹ Borno,Gomina Babagana Zulum; Igbakeji Ọga Agba fun awọn oṣiṣẹ Aarẹ, Ibrahim Hassan-Hadejia; awọn ọmọ ẹgbẹ ile Asofin ti ipinlẹ Jigawa ati awọn agba oṣiṣẹ ijọba fun abẹwo si Hadejia, ipinlẹ Jigawa.

Igbakeji Aarẹ Shettima ṣalaye pe“iku jẹ ohun ti o ti wa ninu akọsilẹ ti o so mọ gbogbo eniyan lọrun, ti kosi ṣee yẹ sibi kankan. Gbogbo wa lawa lati ọdọ Aṣẹda, ti o jẹ pe ti a ba ti de ibusọ ọkọ oju irin pẹlu ẹru wa ti a n duro fun ọkọ. Lati ibo? Lati ọdọ ọlọrun, lọ si ibo, lọ si ọdọ ọlọrun. Awọn apamọwọ ati ẹru wa ni ohun rere ti a ṣe ni ile aye.”

Nigba ti o n sọ pataki abẹwo wọn si ipinlẹ naa, Igbakeji Aarẹ Shettima ṣalaye pe, “Abẹwo yii da lori ibanikẹdun pẹlu rẹ lori iku iya olori ẹbi ti o tun jẹ opo atilẹyin fun ọ ati ti ọmọkunrin rẹ.

 “Ki ọlọrun ko gbabọ wọn si Aljannah Firdaus.”

A gbadura ki ọlọrun ko rọ awọn naa loju lati le ṣagbamọra ipadanu naa,” Igbakeji Aarẹ tun gbadura.

 

Comments are closed.

button