Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ UNICEF Ṣe Ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀rọ Tó Mú Ènìyàn Mí Fún Ìpínlẹ̀ Bauchi.

198

Àjọ àgbáyé fún ìtọjú àwọn ọmọdé UNICEF ti ṣe Ìrànlọ́wọ́ ẹ̀rọ to n ṣe Ìrànlọ́wọ́ fún ènìyàn láti mi daradara fún ìjọba ìpínlẹ̀ Bauchi.

Aṣojú àjọ UNICEF ni orílè-èdè Nàìjíríà Christian Minute ló sọ èyí di mímọ̀ ni ọjọ ìṣẹgun nígbàtí ó gbé ipo silẹ fún elòmíràn Láti tèsíwájú nínú iṣẹ naa ni ilé ìwòsan ìjọba ti o wa ní Azare ni katagun.

Ó sọ di mímọ̀ wí pé anfààní pupọ̀ wà nínú èro yìí fún àwọn ènìyàn, pàápàá jùlọ àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ tuntun ki ìtọ́jú ba lẹ̀ wá lásìkò fún wọn.

Ó wá fi àsìkò náà ró Gómìnà ìpínlẹ̀ Bauchi láti rí wí pé o pèsè agbègbè to dun wo fún ìtọjú àwọn ènìyàn.

Kọmísọ́nà fún ètò ìlera ni ìpínlẹ̀ náà Dókítà Muhammad ṣe ìlérí láti rí wí pé àwọn lo àwọn èrò náà daradara fún ìtọjú àwọn ọmọdé.

Comments are closed.

button