Ìjọba Ìpínlẹ̀ Eko Ní Èróngbà Látí Ṣe Ìrànlọ́wọ́ Abẹ́rẹ́ Àjẹsára Fún Àwon Ènìyàn Tó Tó Mílíọ́nù Méjìdìnlógún.
Ìjọba Ìpínlẹ̀ Eko sọ wí pé o kéré jù àwọn ènìyàn tó tó Mejidinlogun Mílíọ̀nù ni yóò gbà abẹ́rẹ́ àjẹsára láti dènà àrùn rọmọlápárọmọlẹ́sẹ̀, ètò yìí yóò wáyé ní ọjọ́ kankan dilogun oṣù mẹwàá 2024.
Dókítà Abímbólá Bowale, to jẹ akọwe fún ilẹ ìwòsàn ijoba ìpínlẹ̀ Eko, ló sọ èyí di mímọ̀ fún àwọn oníròyìn níbi ìdánilékòó fún àbẹ́rẹ́ àjẹsára.
Ìdánilékòó yìí wáyé ni ọjọ́ Ajé, èyí tí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ṣe agbateru rẹ.
Ó ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàdínlógún ní wọn ó jẹ anfààní abẹ́rẹ́ àjẹsára náà ,èyí tí àjọ ìlera àgbáyé ṣe alátìlẹ́yìn rẹ̀.
Bákanáà àwọn oníròyìn lo anfààní náà láti ṣe ìdánilékòó fún àwọn ènìyàn nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára náà.
Dókítà Akinpelu Adetola tó jẹ alákòóso fún ètò náà sọ wí pé ó ṣe pàtàkì láti gba abẹ́rẹ́ náà fún Ìdènà àrùn rọmọlápárọmọlẹ́sẹ̀.