Kaduna: Ààrẹ Tinubu pàṣẹ kí àwọn elétò ààbò wá àwọn ọmọ ilé ìwé tí wọ́n jígbé rí
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti dari àwọn elétò ààbò ní Nàìjíríà láti sa gbogbo ipá wọn ní ṣíṣàwárí àwọn ọmọ ilé ìwé àti olùkọ́ ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti gíga ti Kuriga, ìpínlẹ̀ Kaduna, tí wọ́n jígbé ní kíákíá.
Igbakeji aarẹ Kashim Shettima ti o sọ eyi di mimọ lasiko ipade kan pẹlu Gomina ipinlẹ naa, Uba Sani, awọn eleto aabo ati awọn to niiṣe, pẹlu awọn ọba ati awọn obi ti ọrọ naa kan an lati ijọba ibilẹ Chikun ti ipinlẹ naa, sọ pe gbogbo agbara to wa nikawọ wọn ni wọn n sa lati ri pe wọn ṣawari awọn ti wọn jigbe.
Igabkeji Shettima wa ṣalaye pe iṣẹlẹ aburu yii dun aarẹ gidi gan ni, ti o si n fi dawọn loju pe aarẹ aarẹ kapa lati daabo bo orilẹ-ede yii.
Gomina ipinlẹ Kaduna, Uba Sani, ti kọkọ sọrọ siwaju nibi ti o ti dupẹ lọwọ aarẹ fun bi o ṣe gbe igbesẹ lori rẹ ati akitiyan to ṣe lati ri pe wọn gba awọn olufaragba silẹ.
O wa n fidiẹ mulẹ pe Tinubu, igbakeji aarẹ Shettima ati awọn eleto aabo ti n ṣiṣẹ papọ pẹlu ijọba ipinlẹ Kaduna lati igba ti iṣẹlẹ aburu yii ti ṣelẹ laarin ọsẹ.
Nigba ti o wa n dupẹ lọwọ igbakeji aarẹ Shettima fun abẹwo rẹ, o wa kilọ ki wọn maa sọ ọrọ naa di toloṣelu, wipe ẹmi awọn ti ọrọ naa kan an ati ibanujẹ ọkan awọn ẹbi wọn yẹ ki o jẹ gbogbo wa logun.
Ọba ilu Chukun, Etsu Chukun, Ishaku Yari, naa wa pe fun afikun awọn eleto aabo, ti o si tun pe fun mimọ ọgba yika awọn ile iwe lagbegbe naa.