Take a fresh look at your lifestyle.

Hajj Ọdún 2024: Ìpínlẹ̀ Èkó Ń Fẹ́ Àtìlẹyìn Àjọ Port Health Service Lórí Abẹ́rẹ́ Àjẹsára

222

 

Àjọ Lagos State Muslim Pilgrims Welfare Board ti pe fún ajọṣepọ pẹlu àjọ Port Health Service (PHS) fún eto  abẹrẹ ajẹsara ati Ipese Káàdì alawọ omi ọsàn lai fi àsìkò sofo fún eto irinajò Umurah ti ọdún yìí.

Akọwe àjọ náà, ọgbẹni Saheed Onipede sọ eyi nigbati o ṣáájú àwọn ọ̀gá agba àjọ náà lọ fún abẹwo ọlọlá sí ọ̀gá agba àjọ Port Health Service, Dokita Omede Ogu, ni ọ́fíìsì rẹ ni pápakọ̀ òfurufú ti Murtala Muhammed ni Ikeja.

Onipede je ko di mimo pe bi ẹgbẹrun méjì ènìyàn to fe lọ sí irinajo Umurah ló ti sàn gbogbo owó wọn to din diẹ ni Mílíọ̀nù Marun-₦4,899,000.00 fun èto ti ọdún yìí.

Ọgbẹni náà wa mu gbogbo àwọn alejo rẹ yika awọn ile ayẹwo tuntun Láàbù ni ọfisiì ikeja, wí pé gbogbo eelo to wa níbẹ̀ ló ni gbogbo awọn ohun àmúyẹ fún ayẹwo eto ìlera ti wọn yóò sì gbe esi ayẹwo sita ni kíámọ́sá.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button