Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Orílè-èdè Nàìjíríà  Ṣe Iranlọwọ Fún Àwọn Àgbẹ̀ Ni Ìpínlẹ̀ Kogi

226

Ìjọba Àpapọ̀ pẹ̀lú ìbáṣepọ̀ ilé iṣé Value Chain Development Programme (VCDP-AF), ni ọjọ́ ajé pin àwọn àwọn ohun èlò ti wọn fi sisé fún àwọn èlò iranlọwọ tó lè ẹgbẹrun márùn -ún láti fi ṣe Iranlọwọ fún iṣé ọgbin Ìresì.

Ilé iṣé IFAD náà o gbeyin láti ṣe atilẹyin fún ìjọba lórí ètò náà

Lára àwọn ohun èlò iranlọwọ tí wọn Pin naa ni ògùn ti mú ohun ọgbin dàgbà lásìkò ohun elo iná solar, Èrò tí fa omi , láti fi ṣe Iranlọwọ fún ọgbin Ìresì.

Kọmísọ́nà fún ètò ògbìn ni ìpínlẹ̀ Kogi , Ọ̀gbẹni Timothy Jonah lo ṣe ètò pin pin àwọn ohun iranlọwọ náà ni ọjọ́ ajé.

Kọmísọ́nà rọ àwọn ènìyàn láti tẹra mọ iṣé wọn labẹ ijoba Gómìnà ìpínlẹ̀ náà Ahmed Ododo,ko bá le tèsíwájú nínú iṣé rẹ ti o n ṣe fún wọn.

Lára àwọn to je anfààní nínú ètò náà Ìyáàfin Victoria Enebi Samuel Atiba àti Ìyáàfin Olushola Adetunji, láti Ajaokuta, Lokoja àti Kabba-Bunu, dupẹ púpọ lọwọ ìjọba, VCDP fún ìrànlọ́wọ́ ọgbin Ìresì.

Comments are closed.

button