Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Grand Alliance, APGA, Labour, LP, áti People’s Democratic Party, PDP ní ìpínlẹ̀ Ebonyi ti fi ẹgbẹ́ wọn sílẹ̀ lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tí ń ṣèjọba All Progressives Congress, APC ní ìparí ọ̀sẹ̀ yìí.
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako ni ipinlẹ naa ti n fi egbẹ wọn silẹ lọ si APC lati igba ti ile ẹjọ giga julọ ti gba ibo gomina Francis Nwifuru wọle.
Voice Of Nigeria jabọ pe oṣu kinni ni oṣu ikore agbawọle fun ẹgbẹ ti n ṣakoso APC ní ipinlẹ Ebonyi.
Laipe yi, ni igbakeji gomina ipinlẹ Ebonyi, Ọmọ Ọba Patricia Obila sọ fun awọn to niiṣe ninu oṣelu nibi apejọ oloṣelu kan pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako lorisirisi to ju miliọnu mẹta lọ lo ti darapọ mọ APC.
Awọn Adari ẹgbẹ alatako ni agbegbe Umuezeoka ati awọn ti o ti ṣiṣẹ fun awọn ẹgbẹ naa ni oniruuru ikọ ni ipele ipinlẹ wa lara awọn to ṣẹṣẹ darapọ mọ wọn.
Alaga ẹgbẹ, Oloye Stanley Okoro Emegha, Komiṣọna fun eto ibaraenisọrọ ati iṣalaye ti ipinlẹ, Jude Okpor ati Alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ezza, Oloye Ogodoali Nome ni o gbawọn wọ APC ni opin ọsẹ, nibi ayẹyẹ kan ti wọn ṣagbekalẹ rẹ fun wọn.