Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọṣepọ̀ Nàìjíríà-Qatar : Ààrẹ Tinubu yan Mínísítà fún ìsúná ní adarí ikọ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

186

Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ti yan Mínísítà fún ètò ọrọ̀ aje àti ìsúná, Ọ̀gbẹ́ni Wale Edun, ní adarí ikọ̀ Nàìjíríà tí yóò ṣojú orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ìjọba Qatari lórí ìṣàfihàn àti ìmúṣẹ ìdókòwò.

Ààrẹ Tinubu kede adari ikọ Naijiria ni ọjọ Aiku, ni aafin Emir  Qatar, lasiko ibuwọlu awọn adehun pataki lọlọkan o jọkan laarin Naijiria ati orilẹ-ede ti n gba wọn lalejo, Qatar.

Lasiko ipade awọn orile-ede mejeeji, aarẹ Tinubu tun fi aaye gba alaye ranpẹ lati ẹnu Minisita fun idagbasoke awọn ohun alumọni ilẹ, Dokita Dele Alake fun Emir Qatar, ti o si ṣalaye lekunrẹrẹ nipa awọn ohun alumọni inu ilẹ to ṣe pataki, bi lithium, ti o wa jakejado orilẹ-ede pẹlu awọn anfaani pataki rẹ lori alumọọni orilẹ-ede.

Comments are closed.

button