Ààbò Lórí Ounjẹ: Àwọn Onímọ̀ Nípa Ọ̀rọ̀ Ounjẹ Àti Sáyẹnsì Ni Àwọn Faramọ Irinṣẹ́ Àyẹwò (Genome Editing).
Àwọn Onímọ̀ nípa ètò ọ̀gbìn oúnjẹ àti Sáyẹnsì ni àwọn faramọ irinṣẹ́ ti wọn n pé Geneme Editing, láti fi yẹ oúnjẹ wò àti ohun ààbò fún ètò ounjẹ.

Àwọn Onímọ̀ Sáyẹnsì sọ wí pé irinṣẹ náà kó ni ìjàmbá ninu lati lo, tí o sí yàrá púpọ nínú ètò ògbìn.
Wọn ní o jẹ irinse ìgbàlódé ti yóò ṣe iranlọwọ fún ètò ògbìn.
Ìlú Abuja ni àwọn Onimọ ti sọ èyí nibi ìpàdé ìdánilékòó ọlọjọ meji to wáyé lórí irinṣẹ náà ati ona láti lo, pẹlu ìbáṣepọ̀ ilé iṣé NABDA ati NEPAD.

Àwọn Onímọ̀ Sáyẹnsì ni, o ṣe pàtàkì láti ṣe ìdánilékòó fún àwọn oníròyìn lori rẹ pẹ̀lú ki gbogbo àgbáyé ba leè mo ìwúlò rẹ.