Igbákejì ààrẹ Shettima ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ tó ń mójútó ìrìn àjò mímọ́ tuntun
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Igbákejì ààrẹ Kashim Shettima ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ tó ń mójútó ìrìn àjò mímọ́ tuntun ní Naijiria NAHCON, tí ó sì ń rọ̀ àwọn olùṣàkóso tuntun náà láti mú ìṣe tuntun wọ iṣẹ́ ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ ní Nàìjíríà.

Nigba ti o n sọrọ lasiko ifilọlẹ igbimọ tuntun naa ni gbọngan aarẹ ni naa ni Villa, ní Abuja, ní Ọjọọru, igbakeji aarẹ wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa fọwọsowọpọ ki wọn o si mu ọna iṣe iṣẹ tuntun wọn iṣẹ igbimọ naa.

Gẹgẹ bi Igbákejì ààrẹ ṣe sọ, ṣiṣiṣẹ fun igbimọ ẹgbẹ NAHCON, ṣe pataki gidi ganan ni nito ri pe “Hajj jẹ ikan lara opo Isilaamu.”
“Fun yin, yiyan yii jẹ ohun to jẹ oriire fun yin, nitori pe ti ẹ ba ṣe iṣẹ yii daradara, ọlọrun ọba yoo san yin lẹsan re lọdun to n bọ. Fun idi eyi kii ṣe iṣẹ iṣakoso bi ko ṣe iṣẹ ẹsin,” VP sọ bayii.
